Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 22:25-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ẹ kò gbọdọ̀ gba irú ẹranko bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò kankan láti fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ sí Ọlọ́run yín. A kò ní gbà wọ́n fún yín nítorí pé wọ́n ní àbùkù wọ́n sì díbàjẹ́.’ ”

26. Olúwa sọ fún Mósè pé,

27. “Nígbà tí màlúù bá bímọ, tí àgùntàn bímọ, tí ewúrẹ́ sì bímọ, ọmọ náà gbọdọ̀ wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Láti ọjọ́ kèjọ ni ó ti di ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ àfinásun sí Olúwa.

28. Ẹ má ṣe pa màlúù àti ọmọ rẹ̀ tàbí àgùntàn àti ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.

29. “Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ ọpẹ́ sí Olúwa, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóò fí jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín.

30. Ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà gan an: Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀. Èmi ni Olúwa.

31. “Ẹ pa òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.

32. Ẹ má ṣe ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọdọ̀ mọ̀ mí ní mímọ́. Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.

33. Tí ó sì mú yín jáde láti Éjíbítì wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa.”

Ka pipe ipin Léfítíkù 22