Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 21:16-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Olúwa sì bá Mósè sọ̀rọ̀ pé,

17. “Sọ fún Árónì pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú ìran yín tí ó bá ní àrùn kan kò yẹ láti máa rú ẹbọ ohun jíjẹ́ fún mi.

18. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ sún mọ́ ibi ẹbọ náà. Kò gbọdọ̀ sí afọ́jú tàbí arọ, alábùkù ara tàbí àwọn tí ara wọn kò pé.

19. Kò gbọdọ̀ sí ẹnikẹ́ni yálà ó rọ lápá lẹ́sẹ̀,

20. tàbí tí ó jẹ́ abuké, tàbí tí ó ya aràrá tàbí tí ó ní àìsàn ojú tàbí tí ó ní egbò tàbí tí a ti yọ nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀.

21. Kò gbọdọ̀ sí iran àlùfáà tí ó jẹ́ alábùkù ara tí ó gbọdọ̀ wá fi iná sun ẹbọ sí Ọlọ́run. Nítorí pé ó jẹ́ alábùkù, kò gbọdọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé ẹbọ wá fún Olúwa.

22. Ó lè jẹ́ oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ tàbí èyí tí ó mọ́ jùlọ ṣùgbọ́n torí pé ó ní àbùkù kò gbọdọ̀ sún mọ́ ibi aṣọ títa tàbí pẹpẹ.

23. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ba ibi mímọ́ mi jẹ́ torí pé, Èmi Olúwa ló ti sọ wọ́n di mímọ́.’ ”

24. Wọ̀nyí ni àwọn ohun tí Mósè sọ fún Árónì, àwọn ọmọ Árónì àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Léfítíkù 21