Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 20:2-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ará Ísírẹ́lì tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrin Ísírẹ́lì, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún mólékì, kí wọ́n pa á, kí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa.

3. Èmi tìkarami yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ń ó sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ fún òrìṣà mólékì ó ti ba ibi mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú.

4. Bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá mójú kúrò lára irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún òrìṣà mólékì tí wọn kò sì pa irú ẹni bẹ́ẹ̀.

5. Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀, èmi yóò sì ge wọn kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọn: òun àti gbogbo àwọn tí ó dìjọ ṣe àgbérè tọ òrìṣà mólékì lẹ́yìn.

6. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbérè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀; Èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

7. “ ‘Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

8. Ẹ máa kíyèsí àṣẹ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́: Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.

9. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé bàbá tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé bàbá àti ìyá rẹ̀.

Ka pipe ipin Léfítíkù 20