Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 19:9-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ sa ẹ̀sẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀).

10. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátapáta, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú oko àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

11. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́.“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ tan ara yín jẹ.

12. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké: kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.

13. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dá owó iṣẹ́ alágbàṣe dúró di ọjọ́ kejì.

14. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣépè lé adití: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ fi ohun ìdìgbòlù sí iwájú afọ́jú, ṣùgbọ́n bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ: Èmi ni Olúwa.

15. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúṣàájú sí ẹjọ́ talákà: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn: ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ.

16. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olófofó láàrin àwọn ènìyàn rẹ.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mi aládúgbò rẹ wéwu: Èmi ni Olúwa.

17. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kóríra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládúgbò rẹ wí, kí o má baà jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.

18. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, fẹ́ràn aládúgbò rẹ bí ara rẹ, Èmi ni Olúwa.

19. “ ‘Má a pa àṣẹ mi mọ́.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun ọ̀sìn rẹ máa gùn pẹ̀lú ẹ̀yà mìíràn.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbin dàrúdàpọ̀ oríṣìí irúgbìn méjì sínú oko kan.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ èyí tí a fi oríṣìí ohun èlò ìhunṣọ méjì ṣe.

Ka pipe ipin Léfítíkù 19