Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 19:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Bá gbogbo àpéjọpọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ mímọ́ nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.

3. “ ‘Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá àti bàbá rẹ̀, kí ẹ sì ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

4. “ ‘Ẹ má ṣe yípadà tọ ère òrìsà lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ rọ ère òrìsà idẹ fún ara yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

5. “ ‘Nígbà tí ẹ̀yín bá sì rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, kí ẹ̀yin kí ó se é ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò yín!

6. Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú u náà ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ tàbí ní ọjọ́ kejì; èyí tí ó bá sẹ́kù di ọjọ́ kẹta ni kí ẹ fi iná sun.

7. Bí ẹ bá jẹ nínú èyí tí ó sẹ́kù di ọjọ́ kẹta, àìmọ́ ni èyí jẹ́, kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

8. Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù, nítorí pé ó ti ba ohun mímọ́ Olúwa jẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

9. “ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ sa ẹ̀sẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀).

10. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátapáta, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú oko àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

11. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́.“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ tan ara yín jẹ.

12. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké: kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.

13. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dá owó iṣẹ́ alágbàṣe dúró di ọjọ́ kejì.

14. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣépè lé adití: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ fi ohun ìdìgbòlù sí iwájú afọ́jú, ṣùgbọ́n bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ: Èmi ni Olúwa.

15. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúṣàájú sí ẹjọ́ talákà: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn: ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ.

16. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olófofó láàrin àwọn ènìyàn rẹ.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mi aládúgbò rẹ wéwu: Èmi ni Olúwa.

17. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kóríra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládúgbò rẹ wí, kí o má baà jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.

18. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, fẹ́ràn aládúgbò rẹ bí ara rẹ, Èmi ni Olúwa.

Ka pipe ipin Léfítíkù 19