Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 17:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé:

2. “Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ nìyí:

3. Bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Ísírẹ́lì bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó

4. tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa níwájú àgọ́ ìpàdé: ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn: torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀: ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

Ka pipe ipin Léfítíkù 17