Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 14:32-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀.

33. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé.

34. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kénánì tí mo fi fún yín ni ìní, tí mo sì fí àrùn ẹ̀tẹ̀ sínú ile kan ní ilẹ̀ ìní yín.

35. Kí ẹni tí ó ní ilọ̀ náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ àrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’

36. Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má báà di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò.

37. Yóò yẹ àrùn náà wò, bí àrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ.

38. Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ilẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje.

39. Àlùfáà yóò padà wá yẹ ilé náà wò ní ọjọ́ keje. Bí àrùn náà bá ti tàn ká ara ògiri.

40. Àlùfáà yóò pàṣẹ kí a yọ àwọn òkúta tí àrùn náà ti bàjẹ́ kúrò kí a sì kó wọn dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú.

41. Yóò sì mú kí wọ́n ha ògiri inú ilé náà yíká. Gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà tí ó ti ha ni kí wọ́n kó dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú náà.

42. Òkúta mìíràn ni kí wọ́n fi dípò àwọn tí a ti yọ dànù kí wọ́n sì rẹ́ ilé náà pẹ̀lú àwọn ohun ìrẹ́lé tuntun.

43. “Bí àrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ.

44. Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí àrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́.

45. Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́.

46. “Ẹni tí ó bá wọ inú ilé náà lẹ́yìn tí a ti tì í, yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

47. Ẹni tí ó bá sùn nínú ilé náà tàbí tí ó bá jẹun nínú rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀.

48. “Bí àlùfáà bá wá yẹ̀ ẹ́ wò tí àrùn náà kò gbilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà: kí àlùfáà pe ilé náà ní mímọ́, torí pé àrùn náà ti lọ.

49. Láti sọ ilé yìí di mímọ́. Àlùfáà yóò mú ẹyẹ méjì àti igi sídà òdòdó àti hísópù.

50. Yóò sì pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sorí omi tí ó mọ́ nínú ìkòkò amọ̀.

51. Kí ó ri igi sídà, hísópù, òdòdó àti ààyè ẹyẹ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ òkú ẹyẹ àti omi tí ó mọ́ náà kí ó fi wọ́n ilẹ náà lẹ́ẹ̀méje.

Ka pipe ipin Léfítíkù 14