Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 14:27-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Yóò sì fi ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ wọ́n òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ nígbà méje níwájú Olúwa.

28. Àlùfáà yóò sì mú lára òróró ọwọ́ rẹ̀ sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹṣẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ibi kan náà tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí.

29. Kí àlùfáà fi ìyókù nínú òróró ọwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni náà tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún: láti ṣe ètùtù fún un ní ìwájú Olúwa.

30. Lẹ́yìn náà kí ó fí àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rúbọ níwọn ti agbára rẹ̀ mọ.

31. Ọ̀kan fún ẹbọ ẹṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ: Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú Olúwa ní ìpò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́.”

32. Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀.

33. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé.

34. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kénánì tí mo fi fún yín ni ìní, tí mo sì fí àrùn ẹ̀tẹ̀ sínú ile kan ní ilẹ̀ ìní yín.

35. Kí ẹni tí ó ní ilọ̀ náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ àrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’

36. Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má báà di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò.

37. Yóò yẹ àrùn náà wò, bí àrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ.

38. Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ilẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje.

Ka pipe ipin Léfítíkù 14