Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 14:21-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. “Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹbí, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò pọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òṣùwọ̀n òróró

22. àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun.

23. “Kí ó mú wọn wá ní ọjọ́ kẹjọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ ṣíwájú àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa.

24. Àlùfáà náà yóò sì mú ọ̀dọ́ àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú òróró yóò sì fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì.

25. Kí ó pa ọ̀dọ́ àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kí ó fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún.

26. Àlùfáà yóò sì da díẹ̀ lára òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ osì ara rẹ̀.

27. Yóò sì fi ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ wọ́n òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ nígbà méje níwájú Olúwa.

28. Àlùfáà yóò sì mú lára òróró ọwọ́ rẹ̀ sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹṣẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ibi kan náà tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí.

29. Kí àlùfáà fi ìyókù nínú òróró ọwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni náà tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún: láti ṣe ètùtù fún un ní ìwájú Olúwa.

30. Lẹ́yìn náà kí ó fí àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rúbọ níwọn ti agbára rẹ̀ mọ.

31. Ọ̀kan fún ẹbọ ẹṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ: Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú Olúwa ní ìpò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́.”

Ka pipe ipin Léfítíkù 14