Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 11:6-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ehoro ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n kò ya pátakò ẹsẹ̀: àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín.

7. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹdẹ́ ya pátakò ẹṣẹ̀ ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín.

8. Ẹ má ṣe jẹ ẹran wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn. Àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.

9. “ ‘Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá tí ń gbé inú omi òkun, àti nínú odò: èyíkéyí tí ó bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ́.

10. Ṣùgbọ́n nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń gbé inú òkun àti nínú odò tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́, yálà nínú gbogbo àwọn tí ń rákò tàbí láàrin gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù tí ń gbé inú omi àwọn ni kí ẹ kórìíra.

11. Nígbà tí ẹ ti kórìíra wọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn: ẹ gbọdọ̀ kórìíra òkú wọn.

12. Ohunkóhun tí ń gbé inú omi tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́ gbọdọ̀ já sí ìríra fún yín.

13. “ ‘Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ni ẹ gbọdọ̀ kórìíra tí ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ wọ́n torí pé ohun ìríra ni wọ́n: idì, oríṣìiríṣìi igun,

14. Àwòdì àti onírúurú àṣá,

15. Onírúurú ẹyẹ ìwò,

16. Òwìwí, onírúurú ògòǹgò, onírúurú ẹ̀lúùlú, onírúurú àwòdì,

17. Òwìwí kéékèèkéé, onírúurú òwìwí,

18. Òwìwí funfun àti òwìwí ilẹ̀ pápá, àkàlàmàgbò,

19. akọ, onírúurú oódẹ, atọ́ka àti àdán.

20. “ ‘Gbogbo kòkòrò tí ń fò tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn ni wọ́n jẹ́ ìríra fún yín

21. irú àwọn kòkòrò oníyẹ́ tí wọn sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tí ẹ le Jẹ nìyí: Àwọn kòkòrò tí wọ́n ní ìsẹ́po ẹsẹ̀ láti máa fi fò lórí ilẹ̀.

22. Nínú àwọn wọ̀nyí ni ẹ lè jẹ onírúurú esú, onírúurú ìrẹ̀ àti onírúurú tata.

Ka pipe ipin Léfítíkù 11