17. Òwìwí kéékèèkéé, onírúurú òwìwí,
18. Òwìwí funfun àti òwìwí ilẹ̀ pápá, àkàlàmàgbò,
19. akọ, onírúurú oódẹ, atọ́ka àti àdán.
20. “ ‘Gbogbo kòkòrò tí ń fò tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn ni wọ́n jẹ́ ìríra fún yín
21. irú àwọn kòkòrò oníyẹ́ tí wọn sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tí ẹ le Jẹ nìyí: Àwọn kòkòrò tí wọ́n ní ìsẹ́po ẹsẹ̀ láti máa fi fò lórí ilẹ̀.