Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 11:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé,

2. “Ẹ sọ fún àwọn ara Ísírẹ́lì pé, ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń gbé lórí ilẹ̀ àwọn wọ̀nyí ni ẹ le jẹ.

3. Gbogbo ẹranko tí pátakò ẹsẹ̀ rẹ̀ bá là tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ.

4. “ ‘Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan. Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátakò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ràkunmí ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátakò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́.

Ka pipe ipin Léfítíkù 11