Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 9:17-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde, wọ́n sì dé ìlú wọn ní ọjọ́ kẹ́ta: Gíbíónì, Kéfírà, Béérótù àti Kiriati-jéárímù.

18. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò si kọlù wọ́n, nítorí pé àwọn àgbààgbà ìjọ ènìyàn ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.Gbogbo ènìyàn sì kùn sí àwọn àgbààgbà náà,

19. ṣùgbọ́n gbogbo àwọn olórí dáhùn pé, “Àwa ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, a kò sì lè fọwọ́ kàn wọ́n nísinsinyí.

20. Èyí ní àwa yóò ṣe sí wọn, Àwa yóò dá wọn sí, kí ìbínú kí ó má baà wá sorí wa, nítorí ìbúra tí a búra fún wọn.”

21. Wọ́n tẹ̀ṣíwájú, “Ẹ dá wọn sí, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn jẹ́ gégigégi àti apọnmi fún gbogbo ìlú.” Àwọn àgbààgbà náà sì mú ìlérí wọn sẹ fún wọn.

22. Nígbà náà ni Jósúà pe àwọn ọmọ Gíbíónì jọ pé, “Èé ṣe tí ẹ̀yin fí tàn wá wí pe, ‘Àwa gbé ní ibi tí ó jìnnà sí yín,’ nígbà tí ó jẹ́ pé tòsí wa ní ẹ̀yin ń gbé?

23. Nísinsinyí, ẹ̀yin di ẹni ègún: Ẹ̀yin kò sì ní kúrò ní gégigégi àti apọnmi fún ilé Ọlọ́run mi.”

24. Wọ́n sì dá Jóṣúà lóhùn pé, “Nítorí tí a sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ dájú ṣáká bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, láti fún yín ní gbogbo ilẹ̀ náà, kí ó sì pa gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà run kúrò ní iwájú yín. Nítorí náà, àwa bẹ̀rù ẹ̀mí wa nítorí yín, èyí sì ni ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀.

25. Nísinsinyí, àwa wà ní ọwọ́ yín. Ohunkóhun tí ẹ bá rò pé ó yẹ ó si tọ́ lójú yín ní kí ẹ fi wá ṣe.”

26. Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà sì gbà wọ́n là kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọn kò sì pa wọ́n.

27. Ní ọjọ́ náà ni ó sọ àwọn Gíbíónì di aṣẹ́gi àti apọnmi fún àwọn ará ìlú àti fún pẹpẹ Olúwa ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Báyìí ní wọ́n wà títí di òní yìí.

Ka pipe ipin Jóṣúà 9