Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 9:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì yẹ oúnjẹ wọn wò, wọn kò sì wádìí ní ọwọ́ Olúwa.

15. Nígbà náà ni Jósúà ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wọn láti dá wọn sí, àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn fi ọwọ́ sí àdéhùn náà nípa ṣíṣe ìbúra.

16. Ní ẹ̀yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn ará Gíbíónì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ pé aládùúgbò wọn ni wọ́n, tí ń gbé ní tòsí wọn.

17. Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde, wọ́n sì dé ìlú wọn ní ọjọ́ kẹ́ta: Gíbíónì, Kéfírà, Béérótù àti Kiriati-jéárímù.

18. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò si kọlù wọ́n, nítorí pé àwọn àgbààgbà ìjọ ènìyàn ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.Gbogbo ènìyàn sì kùn sí àwọn àgbààgbà náà,

19. ṣùgbọ́n gbogbo àwọn olórí dáhùn pé, “Àwa ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, a kò sì lè fọwọ́ kàn wọ́n nísinsinyí.

20. Èyí ní àwa yóò ṣe sí wọn, Àwa yóò dá wọn sí, kí ìbínú kí ó má baà wá sorí wa, nítorí ìbúra tí a búra fún wọn.”

21. Wọ́n tẹ̀ṣíwájú, “Ẹ dá wọn sí, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn jẹ́ gégigégi àti apọnmi fún gbogbo ìlú.” Àwọn àgbààgbà náà sì mú ìlérí wọn sẹ fún wọn.

Ka pipe ipin Jóṣúà 9