Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 4:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọjá nínú odò Jọ́dánì tan, Olúwa ṣọ fún Jóṣúà pé,

2. “Yan ọkùnrin méjìlá (12) nínú àwọn ènìyàn, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan,

3. kí o sì pàṣẹ fún wọn pé Ẹ gbé òkúta méjìlá (12) láti àárin odò Jọ́dánì ní ibi tí àwọn àlùfáà dúró sí, kí ẹ sì rù wọn kọjá, kí ẹ sì gbé wọn sí ibi tí ẹ̀yin yóò sùn ní alẹ́ yìí.”

4. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà pe àwọn ọkùnrin méjìlá (12) tí ó ti yàn nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kàn,

5. ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín sí àárin odò Jọ́dánì. Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,

6. kí ó sì jẹ́ àmì láàrin yín. Ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ ọ yín pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’

7. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jọ́dánì kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí a rékọjá a Jọ́dánì, a gé omi Jọ́dáni kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láéláé.”

8. Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bí Jóṣúà ti paláṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé òkúta méjìlá láti àárin odò Jọ́dánì gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bí Olúwa ti sọ fún Jóṣúà; wọ́n sì rù wọ́n kọjá lọ sí ibùdó, ní ibi tí wọ́n ti gbé wọn kalẹ̀.

9. Jóṣúà sì to òkúta méjìlá (12) náà sí àárin odò Jọ́dánì fún ìrántí ní ọ̀kánkán ibi tí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí dúró sí. Wọ́n sì wà níbẹ̀ di òní yìí.

10. Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárin Jọ́dánì títí gbogbo nǹkan tí Olúwa pa láṣẹ Jóṣúà di síṣe ní paṣẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti pàṣẹ fún Jóṣúà. Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá,

Ka pipe ipin Jóṣúà 4