Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 23:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, nígbà tí Olúwa sì ti fún Ísírẹ́lì ní ìsinmi kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká nígbà náà Jóṣúà sì ti di arúgbó.

2. Ó sì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ: àgbààgbà wọn, olórí wọn, adájọ́ àti àwọn ìjòyè, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti pọ̀ ní ọdún èmi ti di arúgbó.

3. Ẹ̀yin tìkára yín sì ti rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀nyí nítorí yín, Olúwa Ọlọ́run yín ni ó jà fún yín.

4. Ẹ rántí bí mo ṣe pín ogún ìní fún àwọn ẹ̀yà yín ní ilẹ̀ orílẹ̀ èdè gbogbo tí ó kù; àwọn orílẹ̀ èdè tí mo ti sẹ́gun-ní àárin Jọ́dánì àti Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.

5. Olúwa Ọlọ́run yín fúnra rẹ̀ yóò lé wọn jáde kúrò ní ọ̀nà yín, yóò sì tì wọ́n jáde ní iwájú yín, ẹ̀yin yóò sì gba ilẹ̀-ìní wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún yín.

6. “Ẹ jẹ́ alágbára gidigidi, kí ẹ sì sọ́ra láti ṣe ìgbọ́ran sí ohun tí a kọ sí inú Ìwé Ofin Mósè, láìyí padà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.

7. Ẹ má ṣe ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tí ó sẹ́kù láàárin yín; ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà wọn tàbí kí ẹ fi wọ́n búra. Ẹ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tàbí ki ẹ tẹríba fún wọn.

8. Ṣùgbọ́n ẹ di Olúwa Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń se tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí.

9. “Olúwa ti lé àwọn orílẹ̀ èdè ńlá àti alágbára kúrò níwájú yín; títí di òní yìí kò sí ẹnìkan tí ó le dojú kọ yín.

10. Ọ̀kan nínú yín lé ẹgbẹ̀rún ọ̀ta, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín jà fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí.

11. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ sọ́ra gidigidi láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín.

12. “Ṣùgbọ́n bí ẹ bá yí padà, tí ẹ sì gba ìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó sẹ́kù lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù láàárin yín, tí ẹ sì ń fọmọ fún ara yín ní ìyàwó, tí ẹ sì bá wọn ní àjọṣepọ̀,

13. Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé Olúwa Ọlọ́run yín kì yóò lé àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí jáde mọ́ kúrò níwájú yín. Dípò èyí, wọn yóò jẹ́ ìkẹkùn àti tàkúté fún un yín, pàsán ní ẹ̀yin yín àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ dáradára yí, èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fi fún yín.

Ka pipe ipin Jóṣúà 23