Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 22:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jóṣúà sì pe àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè

2. ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe gbogbo èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa pàṣẹ, ẹ sì ti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun gbogbo tí mo pàṣẹ.

3. Ẹ kò fi àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ láti ìgbà yí títí di òní, ṣùgbọ́n ẹ ti kíyèsára láti pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́.

4. Nísinsìn yìí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, ẹ padà sí ilẹ̀ yín níbi tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin ní òdì kéjì Jọ́dánì.

5. Ṣùgbọ́n ẹ sọ́ra gidigidi láti pa àṣẹ àti òfin tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin mọ́. Láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, láti rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti gbọ́ràn sí àṣẹ rẹ̀, láti dì í mú ṣinṣin àti láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà yín.”

6. Nígbà náà ni Jóṣúà súre fún wọn, ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn.

7. (Mósè ti fi ilẹ̀ fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní Básánì, Jóṣúà sì ti fún ìdajì ẹ̀yà yóòkù ní ilẹ̀ ní ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn). Jóṣúà súre fún wọn ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn,

8. Ó sì wí pé, “Ẹ padà sí ilẹ̀ ẹ yín pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀ yín, pẹ̀lú agbo ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú fàdákà, wúrà, idẹ àti irin, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ, kí ẹ sì pín ìkógún tí ẹ rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ta yín pẹ̀lú àwọn arákùnrin yín.”

Ka pipe ipin Jóṣúà 22