Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 2:14-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. “Ẹ̀mí wa fún ẹ̀mí in yín!” àwọn ọkùnrin náà mú dá a lójú. “Tí ìwọ kò bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò sì fi òtítọ́ àti àánú bá ọ lò nígbà tí Olúwa bá fún wa ní ilẹ̀ náà.”

15. Nígbà náà ní ó fi okùn sọ̀ wọ́n kalẹ̀ ní ojú u fèrèsé, nítorí ilé tí ó ń gbé wà ní ara odi ìlú.

16. Ó sì ti ṣọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí orí òkè, kí ẹ sì fi ara pamọ́ níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta kí àwọn tí ń lépa yín má baà rí i yín títí tí wọn yóò fi darí. Lẹ́yìn náà kí ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ.”

17. Àwọn arákùnrin náà sì sọ fún un pé, “Kí ọrùn un wa baà lè mọ́ kúró nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú yìí.

18. Nígbà tí àwa bá wọ ilé è rẹ, ìwọ yóò ṣo okùn aláwọ̀ aró yìí sí ojú fèrèsé èyí tí ìwọ fi sọ̀ wá kalẹ̀, kí ìwọ kí ó mú baba rẹ, ìyá rẹ, àwọn arákùnrin in rẹ àti gbogbo ìdílé è rẹ kí wọ́n wá sí inú ilé è rẹ.

19. Bí ẹnikẹ́ni bá jáde sí ìta láti inú ilé è rẹ sí inú ìgboro ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò sì wà ní orí ara rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí i rẹ̀. Fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ilé pẹ̀lú ù rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní órí i wa bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kàn án.

20. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá sọ ohun tí àwá ń se, àwa yóò bọ́ nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú.”

21. Ó dáhùn pé, “Ó dára bẹ́ẹ̀.” “Ẹ jẹ́ kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí ṣọ.” Ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ. Ó sì so okùn òdòdó náà sí ojú u-fèrèsé.

22. Nígbà tí wọ́n kúrò, wọ́n sì lọ sí orí òkè, wọ́n sì dúró ní ibẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́ta, títí àwọn alépa fi wá wọn ní gbogbo ọ̀nà wọ́n sì padà láìrí wọn.

23. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin méjì náà padà. Wọ́n sì ṣọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, wọ odò, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Jóṣúà ọmọ Núnì; wọ́n sì sọ fún un gbogbo ohun tí ó ti sẹlẹ̀ sí wọn.

24. Wọ́n sì sọ fún Jóṣúà, “Nítòótọ́ ni Olúwa tí fi gbogbo ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́; gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà ni ìbẹ̀rù-bojo ti mú nítorí i wa.”

Ka pipe ipin Jóṣúà 2