Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 2:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Jóṣúà ọmọ Núnì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò méjì jáde ní àsírí láti Ṣítímù. Ó sì wí pé, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá Jẹ́ríkò.” Wọ́n sì lọ, wọ́n wọ ilé aṣẹ́wó kan, tí à ń pè ní Ráhábù, wọ́n sì dúró síbẹ̀.

2. A sì sọ fún ọba Jẹ́ríkò, “Wò ó! Àwọn ará Ísírẹ́lì kan wá ibí ní alẹ́ yìí láti wá yọ́ ilẹ̀ yí wò.”

3. Ọba Jẹ́ríkò sì ránṣẹ́ sí Ráhábù pé: “Mú àwọn ọkùnrin nì tí ó tọ̀ ọ́ wá, tí ó wọ inú ilé rẹ jáde wá, nítorí wọ́n wá láti yọ́ gbogbo ilẹ̀ yìí wò ni.”

4. Ṣùgbọ́n obìnrin náà ti mú àwọn ọkùnrin méjì náà, o sì fi wọ́n pamọ́. Ó sì wí pé, “lóótọ́ ní àwọn ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ibi tí wọ́n ti wá.

5. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, nígbà tí ó tó àkókò làti ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè, àwọn ọkùnrin náà sì jáde lọ. Èmi kò sì mọ ọ̀nà tí wọ́n gbà lọ. Ẹ lépa wọn kíákíá. Ẹ̀yin yóò bá wọn.”

6. (Ṣùgbọ́n ó ti mú wọn gòkè àjà, ó sì fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ pòròpòrò ọkà tó tò jọ sí orí àjà.)

7. Àwọn ọkùnrin náà jáde lọ láti lépa àwọn amí náà ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìwọdò Jọ́dánì, bí àwọn tí ń lépa wọn sì ti jáde, wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè.

8. Kí àwọn ayọ́lẹ̀wò náà tó sùn ní alẹ́, ó gòkè tọ̀ wọ́n lọ lókè àjà.

9. Ó sì sọ fún wọn, “Èmi mọ̀ pé Olúwa ti fún un yín ní ilẹ̀ yìí, àti pé ẹ̀rù u yín ti sọ wá di ojo dé ibi pé ìdí gbogbo àwọn tí ó n gbé ilẹ̀ yìí ti di omi nítorí iyín.

10. Àwa ti gbọ́ bí Olúwa ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì; àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Ṣíhónì àti Ógù, àwọn ọba méjèèjì ti Ámórì ti ìlà-oòrùn Jọ́dánì, tí ẹ̀yin parun pátapáta.

11. Bí a ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí; ọkàn an wa pámi, kò sì sí okun kankan fún wa mọ́ nítorí i yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ní ayé.

Ka pipe ipin Jóṣúà 2