Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 17:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Àwọn ẹ̀yà Jósẹ́fù méjèèje sì sọ fún Jóṣúà pé, “Kí ló dé ìwọ fi fún wa ní ìpín ilẹ̀ kan àti ìdá kan ní ìní? Nítorí àwa jẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí Olúwa ti bùkún lọ́pọ̀lọpọ̀.”

15. Jóṣúà dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá pọ̀ bẹ́ẹ̀, tí òkè ìlú Éfúráímù bá kéré fún yin, ẹ gòkè lọ sí igbó kí ẹ sì sán ilẹ̀ òkè fún ara yín ní ibẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Pérísì àti ará Réfì.”

16. Àwọn ènìyàn Jósẹ́fù dáhùn, “Òkè kò tó fún wa, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ará Kénánì tí ó gbé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ ní Bẹti-Ṣánì àti àwọn ìletò àti àwọn tí ń gbé ní àfonífojì Jésírẹ́ẹ́lì ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin.”

17. Ṣùgbọ́n Jóṣúà sọ fún àwọn ilé Jósẹ́fù: fún Éfúráímù àti Mánásè pé, “Lóòtọ́ ni ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ẹ sì jẹ́ alágbára. Ẹ̀yin kí yóò sì ní ìpín kan ṣoṣo.

18. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ orí òkè igbo jẹ́ tiyín pẹ̀lú. Ẹ ṣán ilẹ̀ náà, òpin rẹ̀ yóò jẹ́ tiyín pátapáta. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kénánì ní kẹ̀kẹ́ ogun irin, tí ó sì jẹ́ pé wọ́n ní agbára, ṣíbẹ̀ ẹ lè lé wọn jáde.”

Ka pipe ipin Jóṣúà 17