Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 15:12-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbégbé Òkun ńlá.Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Júdà ní agbo ilé wọn.

13. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Jóṣúà, ó fi ìpín fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè, ipin ní Júdà-Kiriati Áríbà, tí í ṣe Hébúrónì. (Áríbà sì ní baba ńlá Ánákì.)

14. Kélẹ́bù sì lé àwọn ọmọ Ánákì mẹ́ta jáde láti Hébúrónì-Ṣéṣáyì, Áhímónì, àti Tálímáì-ìran Ánákì.

15. Ó sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Débírì (tí à ń pè ní Kiriati Séferì tẹ́lẹ̀).

16. Kélẹ́bù sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Ákísà fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati Séférì, tí ó sì gbà á ní ìgbeyàwó.”

17. Ótíniẹ́lì ọmọ Kénásì, arákùnrin Kélẹ́bù, sì gbà á, báyìí ni Kélẹ́bù sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Ákísà fún un ní ìyàwó.

18. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Ákísà lọ sí ọ̀dọ̀ Ótíniẹ̀lì, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà nàà ni Ákísà sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kélẹ́bù sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”

19. Ó sì dáhùn pé, “Ṣe ojúrere àtàtà fún mi. Níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní ilẹ̀ ní Negefi fun mi ní ìsun omi pẹ̀lú.” Báyìí ni Kélẹ́bù fún un ní ìsun omi ti òkè àti ti ìṣàlẹ̀.

20. Èyí ni ilẹ̀ ini ẹ̀yà àwọn ọmọ Júdà gẹ́gẹ́ bi ìdílé wọn.

21. Ìlú ìpẹ̀kun gúsù ti ẹ̀yà Júdà ní Négéfi ní ààlà Édómù niwọ̀nyí:Kabísélì, Édérì, Jágúrì,

22. Kínà, Dímónà, Ádádà,

23. Kédéṣì, Hásórì, Ítina,

24. Sífì, Télémù, Bíálótì,

25. Hasori-Hádátà, Kerioti-Hésírónì (tí í ṣe Hásórì),

26. Ámámù, Sẹ́mà, Móládà,

27. Hasa-Gádà, Hésímónì, Bẹti-Pélétì,

Ka pipe ipin Jóṣúà 15