Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 14:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìwọ̀nyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà gẹ́gẹ́ bí ogún ní ilẹ̀ Kénánì, tí Élíásérì àlùfáà, Jósúà ọmọ Núnì àti olórí ẹ̀yà àwọn agbo ilé Ísírẹ́lì pín fún wọn.

2. Ìbò ni a fi pín ìní wọn fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn án ààbọ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ọwọ́ Mósè.

3. Mósè ti fún àwọn ẹ̀yà méjì àti ààbọ̀ ní ogún wọn ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Léfì ni kò fi ìní fún ní àárin àwọn tí ó kù.

4. Àwọn ọmọ Jósẹ́fù sì di ẹ̀yà méjì, Mánásè àti Éfíráimù. Àwọn ọmọ Léfì kò gba ìpín ní ilẹ̀ náà bí kò ṣe àwọn ìlú tí wọn yóò máa gbé, pẹ̀lú pápá oko tútù fún ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran wọn.

5. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Ísírẹ́lì pín ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

6. Àwọn ọkùnrin Júdà wá sí ọ̀dọ̀ Jósúà ní Gílígálì. Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnè ti Kénísì wí fún un pé, “Ìwọ rántí ohun tí Olúwa sọ fún Mósè ènìyàn Ọlọ́run ní Kadesi-Báníyà nípa ìwọ àti èmi.

7. Mo jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa rán mi láti Kádesi-Báníyà lọ rin ilẹ̀ náà wò. Mo sì mú ìròyìn wá fún un gẹ́gẹ́ bí o ti dá mi lójú,

8. ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin mi tí wọ́n bá mi lọ mú àyà àwọn ènìyàn já. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi fi gbogbo ọkàn tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run mi.

9. Ní ọjọ́ náà, Mósè búra fún mi pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹsẹ̀ rẹ ti rìn ni yóò jẹ́ ìní rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ láéláé, nítorí pé ìwọ fi tọkàntọkàn wà Pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run mi.’

10. “Bí Olúwa ti ṣe ìlérí, o ti mú mi wà láàyè fún ọdún márùn-úndínláàádọ́ta láti ìgbà tí ó ti sọ fún Mósè. Nígbà tí Ísírẹ́lì ń rìn kiri nínú aṣálẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà sì nìyí lónìí, ọmọ ọgọ́rin ọdún ó lé márùn-ún.

Ka pipe ipin Jóṣúà 14