Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 13:23-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ààlà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni etí odò Jọ́dánì. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ ni ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní agbo ilé ní agbo ilé.

24. Èyí ni ohun tí Mósè ti fi fún ẹ̀yà Gádì, ní agbo ilé ní agbo ilé:

25. Agbègbè ìlú Jásérì, gbogbo ìlú Gílíádì àti ìdajì orílẹ̀ èdè àwọn ọmọ ará Ámónì títí dé Áróérì ní ẹ̀bá Rábà;

26. àti láti Hésíbónì lọ sí Ramati-Mísífà àti Bétónímù, àti láti Móhánáimù sí agbégbé ìlú Débírì,

27. àti ní àfonífojì Bẹti-Hárámù, Bẹti-Nímírà, Súkótìọ àti Sáfónì pẹ̀lú ìyókù agbégbé ilẹ̀ Síhónì ọba Héṣíbónì (ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì, agbégbé rẹ̀ títí dé òpin Òkun Kínẹ́rítì).

28. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ jẹ́ ogún àwọn ọmọ Gádì, ní agbo ilé ní agbo ilé.

29. Èyí ni ohun tí Mósè ti fi fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè, èyí ni pé, fún ìdajì ìdílé irú ọmọ Mánásè, ní agbo ilé ní agbo ilé:

30. Ilẹ̀ náà fẹ̀ dé Máháníámù àti gbogbo Básánì, gbogbo agbégbé ilẹ̀ Ógù ọba Básánì, èyí tí í se ibùgbé Jáírì ní Básánì, ọgọ́ta ìlú,

31. ìdajì Gílíádì, àti Ásítarótù àti Édírérì (àwọn ìlú ọba Ógù ní Básánì). Èyí ni fún irú àwọn ọmọ Mákírì ọmọ Mánásè fún ààbọ̀ àwọn ọmọ Mákírì, ní agbo ilé ní agbo ilé.

32. Èyí ni ogún tí Mósè fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù ní ìhà kéjì Jọ́dánì ní ìlà-oòrùn Jẹ́ríkò.

33. Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yà Léfì, Mósè kò fi ogún fún un; Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní ogún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.

Ka pipe ipin Jóṣúà 13