Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 7:8-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́;ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́.

9. Bí ìkùùku tí i túká, tí í sì fò lọ,bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́.

10. Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́.

11. “Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́,èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi,èmí yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi.

12. Èmi a máa ṣe ejò òkun tàbí erinmi,tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi?

13. Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára,ìtẹ́ mi yóò gbé ẹrù ìráhùn mi pẹ̀lú.

14. Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da ẹ̀gbọ̀n bò mi,ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rù bà mí.

15. Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti soàti ikú ju kí ń wà láàyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ.

16. O ṣú mi, èmi kò le wà títí:jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi.

17. “Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀?Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọ̀kàn rẹ lé e?

18. Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀,ti ìwọ o sì máa dán anwò nígbàkúgbà!

19. Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ,tí ìwọ o fi jọ títí èmi o fi lè dá itọ́ mi mì.

20. Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó se sí ọ.Ìwọ Olùtọ́jú ènìyàn?Èéṣe tí ìwọ fi mí ṣe àmì ìtasi niwájú rẹ,bẹ́ẹ̀ ni èmi si di erù-wúwo sì ara rẹ̀

Ka pipe ipin Jóòbù 7