Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 7:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Sé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀?Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe?

2. Bí ọmọ-ọ̀dọ̀ tí máa ń kanjú bojúwo òjíjìàti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀.

3. Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù,òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi.

4. Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, ‘Èmi wí pé nígbà wo ni èmi ó dìde?’Tí òru yóò sì kọjá? Ó sì tó fún mi láti yí síhìn-ín yí sọ́hùn-únTítí yóò fi di ògúlùtu erùpẹ̀ ti a fi wọ̀ mí ní aṣọ,àwọ̀ mi bù, ó sì di sísun ni.

5. Kòkòrò àti ògúlùtu erúpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ,awọ ara mi bù, o sì di sísun.

6. “Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ,o sì di lílò ní àìní ìrètí.

7. Áà! Ránti pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi;ojú mi kì yóò padà rí rere mọ́.

8. Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́;ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́.

9. Bí ìkùùku tí i túká, tí í sì fò lọ,bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́.

10. Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́.

11. “Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́,èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi,èmí yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi.

12. Èmi a máa ṣe ejò òkun tàbí erinmi,tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi?

Ka pipe ipin Jóòbù 7