Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 4:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ni Élífásì, ará Témà dáhùn wí pé:

2. “Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́?Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ?

3. Kíyèsí i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn,ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le.

4. Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró,ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera.

5. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọ lù ọ́;ara rẹ kò lélẹ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 4