Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 38:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀jùmọ̀ Kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn áńgẹ́lì hó ìhó ayọ̀?

8. “Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkunmọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá,

9. Nígbà tí mo fi àwọ sánmọ̀ ṣe aṣọrẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri se ọ̀já ìgbà nú rẹ̀,

10. Nígbà tí mo ṣe òpin fún-un, tímo sì se bèbè àti ìlẹ̀kùn,

11. Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé,kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?

12. “Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbàọjọ́ rẹ̀ wá ìwọ sì mú ìlà oòrùn mọ ipò rẹ̀,

13. Kí ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lègbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?

14. Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdìamọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.

Ka pipe ipin Jóòbù 38