Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 38:29-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá?Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run?

30. Omi di lile bí òkúta, ojú ibú ńlásì dìlù pọ̀.

31. “Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀Píléyádè dáradára? Tàbí ìwọ le tún di Ìràwọ̀ Óríónù?

32. Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Másárótì jáde wá nígbà àkókò wọn?Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Béárì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?

33. Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run?Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?

34. “Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè déàwọ̀sánmọ̀, kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?

35. Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kíó le lọ, ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ósì wí fún wọn pé, àwa nìyí?

36. Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí ayétàbí tí ó fi òye sínú ọkàn?

37. Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọ̀sánmọ̀? Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,

38. Nígbà tí erupẹ̀ di líle, àtiògúlùtú dípò?

39. “Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí?Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọ̀rọ̀ kìnnìún lọ́rùn,

40. Nígbà tí wọ́n bá ń mọ́lẹ̀ nínú ihòtí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ?

Ka pipe ipin Jóòbù 38