Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 38:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. “Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì Sínóò lọ ríbí, kìwọ sì rí ilé ìṣúrà òjò rí,

23. Tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu,dé ọjọ́ ogun àti ìjà?

24. Ọ̀nà wo ǹi ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ńya, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?

25. Ta ni ó la ipadò fún ẹkun omi, àtiọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

26. Láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tíènìyàn kò sí, ní ihà níbi tí ènìyàn kò sí;

27. Láti tẹ́ ilẹ̀ tútù, aṣálẹ̀ àti ẹgàn lọ́rùnláti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?

Ka pipe ipin Jóòbù 38