Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 38:20-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Tí ìwọ í fi mú un lọ síbi àlá rẹ̀, tíìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀?

21. Ìwọ mọ èyí, nitorí nígbà náà nia bí ọ? Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀.

22. “Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì Sínóò lọ ríbí, kìwọ sì rí ilé ìṣúrà òjò rí,

23. Tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu,dé ọjọ́ ogun àti ìjà?

24. Ọ̀nà wo ǹi ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ńya, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?

25. Ta ni ó la ipadò fún ẹkun omi, àtiọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

26. Láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tíènìyàn kò sí, ní ihà níbi tí ènìyàn kò sí;

27. Láti tẹ́ ilẹ̀ tútù, aṣálẹ̀ àti ẹgàn lọ́rùnláti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?

28. Òjò ha ní baba bí? Tàbí ta ni o bíikùn ìṣẹ ìrì?

29. Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá?Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run?

30. Omi di lile bí òkúta, ojú ibú ńlásì dìlù pọ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 38