Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 38:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ní Olúwa dá Jóòbù lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé:

2. “Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìní ìgbirò ṣuìmọ̀ ní òkùnkùn?

3. Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bíọkùnrin nísinsin yìí, nítorí péèmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dámi lóhùn.

4. “Níbo ni ìwọ wà nígbà ti mo fiìpìnlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye.

5. Ta ni ó fi ìwọ̀ rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọbá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?

6. Lórí ibo ni a gbé kan ìpìnlẹ̀ rẹ̀mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,

Ka pipe ipin Jóòbù 38