Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 36:18-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹmáa bàà tàn ọ́; láti jẹ́ kí títóbi èyà mú ọ sìnà.

19. Ọ̀rọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fidé bá ọ bí? Tàbi ipa agbára rẹ?

20. Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń kéàwọn orilẹ̀ èdè kúrò ní ipò wọn.

21. Máa sọra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀padà sí búrubú; Nítori èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.

22. “Kíyèsí i, Ọlọ́run á gbé-ni-ga nípaagbára rẹ̀; ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí òun?

23. Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un,tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?

24. Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,ti ènìyàn ni yín nínú orin.

25. Olúkúlùkù a máa rí i; ènìyàn amáa wòó ní òkèrè,

26. Kíyèsí i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sìmọ̀ bí ó ti ní òye tó, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.

27. “Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omiọjọ́ sílẹ̀, kí wọn kí ó kán bí òjò ní odò,

28. tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀, tí ó sì fi ńgbìn lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ènìyàn.

29. Pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni lè imọ́ ìtànkáàwọ̀sánmọ̀, tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?

30. Kíyèsí i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ká ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 36