Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 36:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé, wọ́n á sì kú láìní òye.

13. “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní àyékó ìbínú jọ; wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá dà wọ́n.

14. Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú níèwe, ẹ̀mí wọn a sì wà nínú àwọn oníwà Sódómù.

15. Òun gba òtòsì nínú ìpọ́njú wọn,a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínu ìnira wọn.

16. “Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó sì dè ọ lọ látiinú ìhágágá síbi gbòòrò, sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálànínú rẹ̀ ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ a jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.

Ka pipe ipin Jóòbù 36