Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 36:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Elíhù sì tún sọ̀rọ̀ wí pé:

2. “Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fi hàn ọ́nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.

3. Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jínjìn wá,èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.

4. Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèkénítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

5. “Kíyèsí i, Ọlọ́run ni alágbára, kò sìgàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.

6. Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú síṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.

7. Òun kì ímú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo,ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́nwà lórí ìtẹ́; Àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.

8. Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí asì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,

9. Nígbà náà ni o ń sọ àwọn ohun tíwọn ti ṣe fún wọn, wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ́lú ìgbéraga wọn.

10. Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́, ósì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedéédéé.

11. Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín,wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀ra, àti ọdún wọn nínú afẹ́.

12. Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé, wọ́n á sì kú láìní òye.

13. “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní àyékó ìbínú jọ; wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá dà wọ́n.

Ka pipe ipin Jóòbù 36