Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 34:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí,bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò níàwòtán dídì ọgbẹ́.’

7. Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jóòbù,tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?

8. Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ósì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.

9. Nítorí ó sá ti wí pé,‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn,tí yóò fí máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’

10. “Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetí sílẹ̀ sí miẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye:Ódodi fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú àti fúnOlódùmárè, tí yóò fí ṣe àìṣedéédéé!

Ka pipe ipin Jóòbù 34