Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 34:17-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ẹni tí ó kóríra òtítọ́ ha le iṣe olóríbí? Ìwọ ó hà sì dá olóótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?

18. O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ènìyàn búburú ní ìwọ,tàbí fún àwọn ọmọ aládé pé, ìkà ni ẹ̀yin;

19. Ańbọ̀tórí fún ẹni tí kì í ṣójúṣàájú àwọn ọmọ-aládétàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí talákà lọ.Nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?

20. Ní ìṣẹ́jú kán ni wọn ó kú, láàrin ọ̀gànjọ́àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́, wọn a sì kọjá lọ;A sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.

21. “Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa-ọ̀nàènìyàn, òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.

22. Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí ojìjìikú, níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí.

23. Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsíẹnìkan, kí òun kí ó sì mú lọsínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run.

24. Òun ó sì fọ́ àwọn alágbáratúútúú láìní ìwádìí, a sì fi ẹlòmìíràn dípò wọn,

25. nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn, ó sì yíwọn po ní òru; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ́rẹ́ pọ̀.

26. Ó kọlù wọ́n nítorí ìwàbúburú wọn níbi tí àwọn ẹlòmìíràn rí i,

27. nítorí pé wọ́n padà sẹ́yìndà sí i,wọn kò sì fi yè sí ipa ọ̀nà rẹ̀ gbogbo,

28. kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkúnàwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, òunsì gbọ́ igbe ẹkún aláìní

29. ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi? Nígbà tí ó bápa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i?Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe é orilẹ̀ èdè tàbi sí ènìyàn kan ṣoṣo;

30. Kí àgàbàgebè kí ó má báà jọbakí wọn kí ó má di ìdẹ̀wò fún ènìyàn.

31. “Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fúnỌlọ́run pé, èmi jẹ̀bí; èmi kò sì ní ṣẹ̀ mọ́?

Ka pipe ipin Jóòbù 34