Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 34:16-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. “Ǹjẹ́ nisinsìnyí, bí ìwọ bá ní òye, gbọ́ èyí;fetísí ohùn ẹnu mi.

17. Ẹni tí ó kóríra òtítọ́ ha le iṣe olóríbí? Ìwọ ó hà sì dá olóótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?

18. O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ènìyàn búburú ní ìwọ,tàbí fún àwọn ọmọ aládé pé, ìkà ni ẹ̀yin;

19. Ańbọ̀tórí fún ẹni tí kì í ṣójúṣàájú àwọn ọmọ-aládétàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí talákà lọ.Nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?

20. Ní ìṣẹ́jú kán ni wọn ó kú, láàrin ọ̀gànjọ́àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́, wọn a sì kọjá lọ;A sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.

21. “Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa-ọ̀nàènìyàn, òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.

22. Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí ojìjìikú, níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí.

23. Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsíẹnìkan, kí òun kí ó sì mú lọsínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run.

24. Òun ó sì fọ́ àwọn alágbáratúútúú láìní ìwádìí, a sì fi ẹlòmìíràn dípò wọn,

25. nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn, ó sì yíwọn po ní òru; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ́rẹ́ pọ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 34