Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 32:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí dákẹ́ láti dá Jóòbù lóhùn, nítorí ó ṣe olódodo lójú ara rẹ̀.

2. Nígbà náà ni inú bí Élíhù ọmọ Bárákélì ará Búsì, láti ìbátan ìdílé Rámù; ó bínú si Jóòbù nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre.

3. Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jóòbù lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jóòbù lẹ́bi.

4. Ǹjẹ́ Élihù ti dúró tití Jóòbù fi sọ̀rọ̀ tán nitorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní iye ọjọ́.

5. Nígbà tí Élíhù ríi pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú.

6. Élíhù, ọmọ Bárákélì, ará Búsì,dáhùn ó sì wí pé: ọmọdé ní èmiàgbà sì ní ẹ̀yin; Ǹjẹ́ nítorí náàní mo dúró mo sì ń bẹ̀rù láti fiìmọ̀ mi hàn yin.

7. Èmi wí pé ọjọjọ́ ni ìbá sọ̀rọ̀, àtiọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.

8. Ṣùgbọ́n ẹ̀mi kan ní ó wà nínúènìyàn àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.

9. Ènìyàn ńláńlá kì íṣe ọlọ́gbọ́n,Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.

10. “Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé: Ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi;èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.

11. Kíyèsí i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín;Èmi fetísí àròyé yín, nígbà tíẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀nyín yóò sọ;

Ka pipe ipin Jóòbù 32