Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 28:7-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojúgúnnugún kò rí i rí;

8. Àwọn ẹrankan agbéraga kò rìn ibẹ̀rí, bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.

9. Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkèńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.

10. Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta,ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.

11. Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún—kún-ya, ó sì mú ohun tí ópamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.

12. “Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wáọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe?

13. Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.

14. Ọ̀gbun wí pé, kò sí nínú mi;omi òkun sì wí pé, kò si nínú mi.

15. A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kòle è fi òsùnwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.

16. A kò le è fi wúrà Ófírì, tàbíòkútà Óníkísì iyebíye, tàbí òkúta Sáfírì díye lé e.

17. Góòlù àti òkúta Kírísítalì kò tóẹgbẹ́rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èló wúrà ṣe pàsípààrọ̀ rẹ̀.

18. A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta Jásípérì;iye ọgbọ́n sì ju òkúta Rubì lọ.

19. Òkùta tópásì ti Kúsì kò tóẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.

20. “Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá?Tàbí níbo ni òye ń gbé?

21. A rí i pé, ó farasinko kúrò ní ojúàwọn alààyè gbogbo, ó sì fara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.

22. Ibi ìparun (Ábádónì) àti ikú wípé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.

Ka pipe ipin Jóòbù 28