Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 28:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ibi ìparun (Ábádónì) àti ikú wípé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.

23. Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nàrẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé

24. Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ósì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,

25. Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fiòṣùwọ̀n wọ̀n omi.

26. Nígbà tí ó pàsẹ fún òjò, tí ó sì laọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

27. Nígbà náà ni órí i, ó sì sọ ọ́ jáde;ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.

Ka pipe ipin Jóòbù 28