Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 28:11-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún—kún-ya, ó sì mú ohun tí ópamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.

12. “Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wáọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe?

13. Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.

14. Ọ̀gbun wí pé, kò sí nínú mi;omi òkun sì wí pé, kò si nínú mi.

15. A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kòle è fi òsùnwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.

16. A kò le è fi wúrà Ófírì, tàbíòkútà Óníkísì iyebíye, tàbí òkúta Sáfírì díye lé e.

17. Góòlù àti òkúta Kírísítalì kò tóẹgbẹ́rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èló wúrà ṣe pàsípààrọ̀ rẹ̀.

18. A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta Jásípérì;iye ọgbọ́n sì ju òkúta Rubì lọ.

19. Òkùta tópásì ti Kúsì kò tóẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.

20. “Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá?Tàbí níbo ni òye ń gbé?

21. A rí i pé, ó farasinko kúrò ní ojúàwọn alààyè gbogbo, ó sì fara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.

22. Ibi ìparun (Ábádónì) àti ikú wípé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.

23. Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nàrẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé

24. Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ósì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,

25. Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fiòṣùwọ̀n wọ̀n omi.

26. Nígbà tí ó pàsẹ fún òjò, tí ó sì laọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

27. Nígbà náà ni órí i, ó sì sọ ọ́ jáde;ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.

28. Àti fún ènìyàn ni ó wí pé,‘Kíyè sí i ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n, àtiláti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.’ ”

Ka pipe ipin Jóòbù 28