Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 27:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀,nígbà tí ìpọ́jú bá dé sí i?

10. Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè?Òun ha lé máa képe Ọlọ́run nígbà gbogbo?

11. “Èmi ó kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ ní ti ọwọ́ Ọlọ́run:ọ̀nà tí ńbẹ lọ́dọ̀Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pamọ́.

12. Kíyèsí i, gbogbo yín ni ó ti rí i;nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe já sí asán pọ̀ bẹ́ẹ̀?

13. “Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti ogún àwọnaninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmáre:

14. Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fúnidà ni; àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ.

Ka pipe ipin Jóòbù 27