Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 27:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pẹ̀lúpẹ̀lú Jóòbù sì tún sọ kún ọ̀rọ̀ òwe rẹ̀, ó sì wí pé:

2. “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, ẹni tí ógba ìdájọ́ mi lọ, àti Olódùmárè tí ó bà mi ní ọkàn jẹ́;

3. (Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi ń bẹ nínúmi, àti tí ẹ̀mi Ọlọ́run ń bẹ nínú ihò imú mi.)

4. Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ èké, Bẹ́ẹ̀ niahọ́n mi kì yóò sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

5. Kí a má ríi pé èmi ń dá yín láre;títí èmi ó fi kú, èmi kì yóò sí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi.

6. Òdodo mi ni èmi dìmú ṣinṣin,èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́; àyàmi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi.

7. “Kí ọ̀ta mi kí ó dàbí ènìyànbúburú, àti ẹni tí ń dìde sími kí ó dàbí ẹni aláìsòdodo.

8. Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè,nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde?

9. Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀,nígbà tí ìpọ́jú bá dé sí i?

10. Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè?Òun ha lé máa képe Ọlọ́run nígbà gbogbo?

Ka pipe ipin Jóòbù 27