Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 26:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣùgbọ́n Jóòbù sì dáhùn wí pé:

2. Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tíkò ní ipá, báwo ní ìwọ ń ṣe gbà apá ẹni tí kò ní agbára?

3. Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ ẹni tí kòní ọgbọ́n, tàbí báwo ní ìwọ sọdi ọ̀ràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí ó ti rí?

4. Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọnọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti ẹ̀mi ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?

5. “Àwọn aláìlágbára ti iṣà òkúwárìrì, lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

6. Ìhòòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run,ibi ìparun kò sí ní ibojì.

7. Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibiòfùrufú, ó sì fi ayé rọ̀ ní ojú òfo.

Ka pipe ipin Jóòbù 26