Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 24:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Se bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmárè fún ìdájọ́, èéṣe tíojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀?

2. Díẹ̀ nínú wọn a ṣún àmì ààlà ilẹ̀,wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n sì ji wọn.

3. Wọ́n á sì dà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní babalọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá-màlúù opó ní ohun ògo.

4. Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà,àwọn talákà àyé a sá pamọ́ pọ̀.

5. Kíyèsí i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ nínú ijùni àwọn talákà ijáde lọ sí iṣẹ́wọn; Wọ́n a tètè dìde láti wáohun ọdẹ; ijù pèsè oúnjẹ fúnwọn àti fún àwọn ọmọ wọn

6. Olúkulùkù a sì ṣa ọkà oúnjẹ ẹranrẹ̀ nínú oko, wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú.

7. Ní hòòhò ni wọn má a sùn láìní aṣọ,tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù.

8. Ọ̀wàrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n,wọ́n sì lẹ̀mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò.

Ka pipe ipin Jóòbù 24