Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 22:25-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Nígbà náà ní Olódùmáarè yóò jẹ́wúrà rẹ, àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

26. Lótìítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inúdídùn nínú Olódùmáarè, ìwọ ósì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.

27. Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀,yóò sì gbọ́ tìrẹ, ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.

28. Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú,yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ; ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ.

29. Nígbà tí ipa-ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀,nígbà náà ni ìwọ o wí pé, ‘Ìgbésókè ń bẹ!’Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là!

30. Yóò gba ẹni tí kì í iṣe aláìjẹ̀bi là,a ó sì gbà á nípa mímọ́ ọwọ́ rẹ̀.”

Ka pipe ipin Jóòbù 22