Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 22:20-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Lótìítọ́ àwọn ọ̀ta wa ni a ké kúrò, ináyóò sì jó oró wọn run.

21. “Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sìrí àlàáfíà; Pẹ̀lú rẹ̀ nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.

22. Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀wá, kí o sì tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.

23. Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀Olódùmáarè, a sì gbé ọ ró, bíìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,

24. Tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀lórí erùpẹ̀ àti wúrà ófiri lábẹ́ òkúta odò,

25. Nígbà náà ní Olódùmáarè yóò jẹ́wúrà rẹ, àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

26. Lótìítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inúdídùn nínú Olódùmáarè, ìwọ ósì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Ka pipe ipin Jóòbù 22