Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 22:2-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run?Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀?

3. Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmáarèpé, olódodo ni ìwọ? Tàbí èrèkí ni fún un, ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé?

4. “Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rùỌlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí?

5. Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi, àti ẹ̀ṣẹ̀rẹ láìníye?

6. Nítòótọ́ ìwọ bèèrè fún ààbò niọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí, ìwọsì tú oníhòhò ní aṣọ wọn.

7. Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu, ìwọsì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa.

8. Bí ó ṣe ti alágbára nì ni, òun ni óní ilẹ̀, ọlọ́lá sì tẹ̀dó sínú rẹ̀.

9. Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ níọwọ́ òfo; Apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́.

10. Nítorí náà ni ìdẹkùn ṣe yí ọkáàkiri, àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu,

11. Èé ṣe tí òkùnkùn, fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tíìwọ kò fi lè ríran; Èé ṣe tíọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12. “Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run?Ṣá wò orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!

13. Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀?Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?

Ka pipe ipin Jóòbù 22