Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 22:15-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ìwọ fẹ́ rìn ìpa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọnènìyàn búburú tí rìn?

16. A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayéláìpé ọjọ́ wọn; ìpilẹ̀ wọn ti dé bí odò síṣàn;

17. Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé,lọ kúrò lọ́dọ̀ wa! Kí niOlódùmárè yóò ṣe fún wọn?

18. Ṣíbẹ̀ ó fi ohun rere kún ilé wọn!Ṣùgbọ́n ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi!

19. “Àwọn olódodo rí ìparun wọn,wọ́n sì yọ̀, àwọn aláìlẹ̀ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn ín ẹlẹ́yà pé,

20. Lótìítọ́ àwọn ọ̀ta wa ni a ké kúrò, ináyóò sì jó oró wọn run.

21. “Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sìrí àlàáfíà; Pẹ̀lú rẹ̀ nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.

22. Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀wá, kí o sì tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.

23. Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀Olódùmáarè, a sì gbé ọ ró, bíìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,

Ka pipe ipin Jóòbù 22