Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 22:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí náà ni ìdẹkùn ṣe yí ọkáàkiri, àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu,

11. Èé ṣe tí òkùnkùn, fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tíìwọ kò fi lè ríran; Èé ṣe tíọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12. “Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run?Ṣá wò orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!

13. Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀?Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?

14. Àwọ̀sánmọ̀ tí ó nípọn ni ìborafún un, tí kò fi lè ríran; ó sì rìn nínú àyíká ọ̀run.

15. Ìwọ fẹ́ rìn ìpa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọnènìyàn búburú tí rìn?

16. A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayéláìpé ọjọ́ wọn; ìpilẹ̀ wọn ti dé bí odò síṣàn;

17. Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé,lọ kúrò lọ́dọ̀ wa! Kí niOlódùmárè yóò ṣe fún wọn?

Ka pipe ipin Jóòbù 22